1 Kings 2:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Joabu gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó sá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, ó sì di ìwo pẹpẹ mú, nítorí pé lẹ́yìn Adonija ni ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí lẹ́yìn Absalomu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ihin si de ọdọ Joabu: nitori Joabu ti tọ̀ Adonijah lẹhin, ṣugbọn kò tọ̀ Absalomu lẹhin: Joabu si sá sinu agọ Oluwa, o si di iwo pẹpẹ mu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Jóábù, ẹni tí ó ti dìtẹ̀ pẹ̀lú Àdóníjà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wà pẹ̀lú Ábúsálómù, ó sì sá lọ sínú àgọ́ OLÚWA, ó sì di ìwo pẹpẹ mú.