1 Kings 2:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣe gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun rẹ pa láṣẹ fún ọ pé kí o ṣe, máa tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀, sì pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ sinu ìwé òfin Mose, kí gbogbo ohun tí o bá ń ṣe lè máa yọrí sí rere, níbikíbi tí o bá n lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si pa ilana Oluwa, Ọlọrun rẹ mọ, lati ma rin li ọ̀na rẹ̀, lati pa aṣẹ rẹ̀ mọ, ati ofin rẹ̀, ati idajọ, rẹ̀ ati ẹri rẹ̀ gẹgẹ bi a ti kọ ọ ni ofin Mose, ki iwọ ki o lè ma pọ̀ si i ni ohun gbogbo ti iwọ o ṣe, ati nibikibi ti iwọ ba yi ara rẹ si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
kí o sì wòye ohun tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ béèrè, rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí o sì pa àṣẹ àti òfin rẹ̀ mọ́, àti ìdájọ́ rẹ, àti ẹ̀rí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé òfin Mósè, nítorí kí ìwọ kí ó le è máa ṣe rere ní ohun gbogbo tí ìwọ ṣe, àti ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ,