1 Kings 2:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọba dá a lóhùn pé, “Ṣe bí Joabu ti ní kí o ṣe. Pa á, kí o sì sin ín. Nígbà náà ni ọrùn èmi, ati arọmọdọmọ Dafidi yóo tó mọ́ kúrò ninu ohun tí Joabu ṣe nígbà tí ó pa àwọn aláìṣẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si wi fun u pe, Ṣe gẹgẹ bi o ti wi ki o si kọlù u, ki o si sin i, ki iwọ ki o le mu ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kuro lọdọ mi ati kuro lọdọ ile baba mi, ti Joabu ti ta silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì pàṣẹ fún Bénáyà pé, “Ṣe bí ó ti wí. Kọ lù ú, kí o sì sin ín, kí o sì mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi àti kúrò lọ́dọ̀ ilé bàbá mi, tí Jóábù ti ta sílẹ̀.