1 Kings 2:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA yóo jẹ Joabu níyà fún àwọn eniyan tí ó pa láìjẹ́ pé Dafidi baba mí mọ ohunkohun nípa rẹ̀. Ó pa Abineri, ọmọ Neri, ọ̀gágun àwọn ọmọ ogun Israẹli ati Amasa, ọmọ Jeteri, ọ̀gágun àwọn ọmọ ogun Juda. Àwọn mejeeji tí ó pa láìṣẹ̀ yìí ṣe olóòótọ́ ju òun pàápàá lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa yio si yi ẹ̀jẹ rẹ̀ pada sori rẹ̀, nitoriti o kọlù ọkunrin meji ti o ṣe olododo, ti o sàn jù on tikararẹ̀ lọ, o si fi idà pa wọn. Dafidi baba mi kò si mọ̀, ani, Abneri, ọmọ Neri, olori ogun, ati Amasa, ọmọ Jeteri, olori ogun Juda.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA yóò sì san ẹ̀jẹ̀ tí ó ti ta sílẹ̀ padà fún un, nítorí tí ó kọlu ọkùnrin méjì, ó sì fi idà rẹ̀ pa wọ́n, Dáfídì bàbá mi kò sì mọ̀ àwọn méjèèjì ni. Ábínérì ọmọ Nérì olórí ogun Ísírẹ́lì, àti Ámásà ọmọ Jétérì olórí ogun Júdà, wọ́n jẹ́ olódodo, wọ́n sì sàn ju òun fúnrarẹ̀ lọ.