1 Kings 2:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí o bá ń gbọ́ ti OLUWA, OLUWA yóo pa ìlérí tí ó ṣe nípa mi mọ́, pé arọmọdọmọ mi ni yóo máa jọba ní Israẹli níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá pa òfin òun mọ tọkàntọkàn, pẹlu òtítọ́ inú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki Oluwa ki o le mu ọ̀rọ rẹ̀ duro ti o ti sọ niti emi pe: Bi awọn ọmọ rẹ ba kiyesi ọ̀na wọn, lati mã fi gbogbo aiya wọn, ati gbogbo ọkàn wọn, rìn niwaju mi li otitọ, (o wipe), a kì yio fẹ ọkunrin kan kù fun ọ lori itẹ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
kí OLÚWA kí ó lè pa ìlérí rẹ̀ tí ó sọ nípa tèmi mọ́ pé: ‘Bí àwọn ọmọ rẹ bá kíyèsí ọ̀nà wọn, tí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà wọn àti ọkàn wọn rìn níwájú mi ní òtítọ́, o kì yóò sì kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.’