1 Kings 2:42 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ó ranṣẹ pè é, ó bi í pé, “Ṣebí o búra fún mi ní orúkọ OLUWA pé o kò ní jáde kúrò ní Jerusalẹmu? Mo sì kìlọ̀ fún ọ pé, ní ọjọ́ tí o bá jáde, pípa ni n óo pa ọ́. O gbà bẹ́ẹ̀, o sì ṣèlérí fún mi pé o óo pa òfin náà mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si ranṣẹ, o si pè Ṣimei, o si wi fun u pe, emi kò ti mu ọ fi Oluwa bura, emi kò si ti fi ọ ṣe ẹlẹri, pe, Li ọjọ ti iwọ ba jade, ti iwọ ba si rìn jade lọ nibikibi, ki iwọ ki o mọ̀ dajudaju pe, kikú ni iwọ o kú? iwọ si wi fun mi pe, Ọrọ na ti mo gbọ́, o dara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba pe Síméì lẹ́jọ́, ó wí fún un pé, “Ǹjẹ́ èmi kò ti mú ọ búra ní ti OLÚWA, èmi sì ti kìlọ̀ fún ọ pé, ‘Ní ọjọ́ tí ìwọ bá kúrò láti lọ sí ibikíbi, kí o mọ̀ dájú pé ìwọ yóò kú’? Nígbà náà ni ìwọ sì sọ fún mi pé, ‘Ohun tí ìwọ sọ dára. Èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn.’