1 Kings 2:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ṣugbọn òtítọ́ inú ni kí o máa fi bá àwọn ọmọ Basilai ará Gileadi lò. Jẹ́ kí wọ́n wà lára àwọn tí yóo máa bá ọ jẹun pọ̀, nítorí pé òótọ́ inú ni wọ́n fi wá pàdé mi ní àkókò tí mò ń sá lọ fún Absalomu, arakunrin rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ki o ṣe ore fun awọn ọmọ Barsillai, ara Gileadi, ki o si jẹ ki nwọn ki o wà ninu awọn ti o jẹun lori tabili rẹ: nitori bẹ̃ni nwọn ṣe tọ̀ mi wá nigbati mo sá kuro niwaju Absalomu, arakunrin rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣùgbọ́n fi inú rere hàn sí àwọn ọmọ Bárísíláì, ti Gílíádì, jẹ́ kí wọn wà lára àwọn tí ó ń jẹun lórí tábìlì rẹ̀. Wọ́n dúró tì mí nígbà tí mo sá kúrò níwájú Ábúsálómù arákùnrin rẹ̀.