1 Kings 2:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ṣimei ọmọ Gera ará Bahurimu láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, èpè burúkú ni ó ń gbé mi ṣẹ́ lemọ́lemọ́ ní ọjọ́ tí mo lọ sí Mahanaimu. Ṣugbọn nígbà tí ó wá pàdé mi létí odò Jọdani, mo jẹ́jẹ̀ẹ́ fún un ní orúkọ OLUWA pé, n kò ní pa á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si wò o, Ṣimei, ọmọ Gera, ẹyà Benjamimi ti Bahurimu, wà pelu rẹ ti o bú mi ni ẽbu ti o burujù, ni ọjọ́ ti mo lọ si Mahanaimu: ṣugbọn o sọkalẹ wá pade mi ni Jordani, mo si fi Oluwa bura fun u pe, Emi kì yio fi idà pa ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àti kí o rántí, Ṣíméhì ọmọ Gérà ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì tí Báhúrímù wà pẹ̀lú rẹ̀, tí ó bú mi ní èébú tí ó korò ní ọjọ́ tí mo lọ sí Máhánáímù. Nígbà tí ó sọ̀kalẹ̀ wá pàdé mi ní Jọ́dánì, mo fi OLÚWA búra fún un pé: ‘Èmi kì yóò fi idà pa ọ́.’