1 Kings 20:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Benhadadi, ọba Siria kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ; àwọn ọba mejilelọgbọn ni wọ́n wá láti ràn án lọ́wọ́, pẹlu gbogbo ẹṣin, ati gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun wọn. Wọ́n dó ti ìlú Samaria, wọ́n sì bá a jagun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
BENHADADI, oba Siria si gbá gbogbo ogun rẹ̀ jọ: ọba mejilelọgbọn si mbẹ pẹlu rẹ̀ ati ẹṣin ati kẹkẹ́: o si gokè lọ, o si dóti Samaria, o ba a jagun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹni-Hádádì ọba Árámù sì gbá gbogbo ogun rẹ̀ jọ. Ọba méjìlélọ́gbọ̀n sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ àti ẹsin àti kẹ̀kẹ́, ó sì gòkè lọ, ó sì dóti Samáríà, ó sì kọlù ú.