1 Kings 20:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Benhadadi ọba tún ranṣẹ pada pé, “Àwọn oriṣa ń gbọ́! Mò ń kó àwọn eniyan bọ̀ láti pa ìlú Samaria run, wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé ọwọ́ lásán ni wọn yóo fi kó gbogbo erùpẹ̀ ìlú náà. Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, kí àwọn oriṣa pa mí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Benhadadi si ranṣẹ si i, o si wipe, Ki awọn oriṣa ki o ṣe bẹ̃ si mi, ati jù bẹ̃ lọ pẹlu bi ẽkuru Samaria yio to fun ikunwọ fun gbogbo enia ti ntẹle mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹni-Hádádì sì tún rán oníṣẹ́ mìíràn sí Áhábù wí pé, “kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú bí eekuru Samáríà yóò tó fún ìkúnwọ́ fún gbogbo ènìyàn tí ń tẹ̀lé mi.”