1 Kings 20:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Benhadadi gbọ́ iṣẹ́ yìí níbi tí ó ti ń mu ọtí pẹlu àwọn ọba yòókù ninu àgọ́, ó pàṣẹ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé kí wọ́n lọ múra ogun. Wọ́n bá múra láti bá Samaria jagun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati Benhadadi gbọ́ ọ̀rọ yi, bi o ti nmuti, on ati awọn ọba ninu agọ, li o sọ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ tẹ́gun si ilu na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹni-Hádádì sì gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí nigbà tí òun àti àwọn ọba ń mu ọtí nínú àgọ́ wọn, ó sì pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé, “Ẹ tẹgun sí ìlú náà.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe tan láti kọlu ìlú náà.