1 Kings 20:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ahabu bèèrè pé, “Ta ni yóo ṣáájú ogun?” Wolii náà dáhùn pé, “OLUWA ní, àwọn iranṣẹ gomina ìpínlẹ̀ ni.” Ahabu tún bèèrè pé, “Ta ni yóo bẹ̀rẹ̀ ogun náà?” Wolii náà dáhùn pé, “Ìwọ gan-an ni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ahabu wipe, Nipa tani? On si wipe, Bayi li Oluwa wi, Nipa awọn ipẹrẹ̀ awọn ijoye igberiko. Nigbana li o wipe, Tani yio wé ogun na? On si dahùn pe: Iwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Áhábù sì béèrè pé, “Ṣùgbọ́n ta ni yóò ṣe èyí?” Wòlíì náà sì dáhùn wí pé, “Ìwọ ni yóò ṣe é.”