1 Kings 20:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba bá pe gbogbo àwọn iranṣẹ tí wọ́n wà lábẹ́ àwọn gomina ìpínlẹ̀ jọ, gbogbo wọn jẹ́ ojilerugba ó dín mẹjọ (232), ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli jọ, gbogbo wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaarin (7,000).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li o kà awọn ipẹrẹ̀ awọn ijoye igberiko, nwọn si jẹ igba o le mejilelọgbọn: lẹhin wọn li o si kà gbogbo awọn enia, ani gbogbo awọn ọmọ Israeli jẹ ẹdẹgbarin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Áhábù ka àwọn ìjòyè kéékèèkéé ìgbéríko, wọ́n sì jẹ́ igba ó lé méjìlélọ́gbọ̀n. (232) Nígbà náà ni ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù jọ, gbogbo wọn sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin. (700)