1 Kings 20:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wolii náà tún tọ Ahabu ọba lọ, ó wí fún un pé, “Pada lọ kó àwọn ọmọ ogun rẹ jọ, kí o sì ṣètò dáradára; nítorí pé, ọba Siria yóo tún bá ọ jagun ní ìbẹ̀rẹ̀ àkókò òjò.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Woli na si wá sọdọ ọba Israeli, o si wi fun u pe, Lọ, mu ara rẹ giri, ki o si mọ̀, ki o si wò ohun ti iwọ nṣe: nitori li amọdun, ọba Siria yio goke tọ̀ ọ wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn náà, wòlíì náà sì wá sọ́dọ̀ ọba Ísírẹ́lì, ó sì wí pé, “Lọ, mú ara rẹ gírí, kí o sì mọ̀, kí o sì wo ohun tí ìwọ yóò ṣe, nítorí ní àmọ́dún ọba Árámù yóò tún gòkè tọ̀ ọ́ wá.”