1 Kings 20:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn oníṣẹ́ Benhadadi ọba wí fún un pé, “Oriṣa orí òkè ni oriṣa àwọn ọmọ Israẹli. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ṣẹgun wa. Ṣugbọn bí a bá gbógun tì wọ́n ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, a óo ṣẹgun wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn iranṣẹ ọba Siria si wi fun u pe, ọlọrun wọn, ọlọrun oke ni; nitorina ni nwọn ṣe li agbara jù wa lọ; ṣugbọn jẹ ki a ba wọn jà ni pẹtẹlẹ, awa o si li agbara jù wọn lọ nitõtọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ìránṣẹ́ ọba Árámù sì wí fún un pé, “Ọlọ́run wọn, Ọlọ́run òkè ni. Ìdí nìyìí tí wọ́n ṣe ní agbára jù wá lọ. Ṣùgbọ́n bí a bá bá wọn jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àwa yóò ní agbára jù wọ́n lọ dájúdájú.