1 Kings 20:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí o wá kó àwọn ọmọ ogun mìíràn jọ, kí wọ́n pọ̀ bí i ti àkọ́kọ́, kí ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun pọ̀ bákan náà. A óo bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní pẹ̀tẹ́lẹ̀; láìsí àní àní, a óo sì ṣẹgun wọn.” Ọba Benhadadi gba ìmọ̀ràn wọn, ó sì ṣe ohun tí wọ́n wí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si kà iye ogun fun ara rẹ gẹgẹ bi ogun ti o ti fọ́, ẹṣin fun ẹṣin, ati kẹkẹ́ fun kẹkẹ́: awa o si ba wọn jà ni pẹ̀tẹlẹ, nitõtọ awa o li agbara jù wọn lọ. O si fi eti si ohùn wọn, o si ṣe bẹ̃.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí o sì tún kó ogun jọ fún ara rẹ bí èyí tí ó ti sọnù; ẹṣin fún ẹṣin, kẹ̀kẹ́ fún kẹ̀kẹ́; kí a bá lè bá Ísírẹ́lì jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Nítòótọ́ àwa yóò ní agbára jù wọ́n lọ.” Ó sì gba ti wọn, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.