1 Kings 20:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n kó àwọn ọmọ ogun Israẹli náà jọ, wọ́n sì wá àwọn ohun ìjà ogun fún wọn. Àwọn náà jáde sójú ogun, wọ́n pàgọ́ tiwọn siwaju àwọn ọmọ ogun Siria, wọ́n wá dàbí agbo ewúrẹ́ meji kéékèèké níwájú àwọn ọmọ ogun Siria tí wọ́n tò lọ rẹrẹẹrẹ ninu pápá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si ka iye awọn ọmọ Israeli, nwọn si pese onjẹ, nwọn si lọ ipade wọn: awọn ọmọ Israeli si dó niwaju wọn gẹgẹ bi agbo ọmọ ewurẹ kekere meji: ṣugbọn awọn ara Siria kún ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí a sì ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì pèsè oúnjẹ, wọ́n sì lọ pàdé wọn. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dó níwájú wọn gẹ́gẹ́ bí agbo ọmọ ewúrẹ́ kékeré méjì, nígbà tí àwọn ará Árámù kún ilẹ̀ náà.