1 Kings 20:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wolii kan tọ Ahabu lọ, ó sì wí fún un pé, “OLUWA ní kí n wí fún ọ pé, ‘Nítorí pé àwọn ará Siria sọ pé, “ọlọrun orí òkè ni OLUWA, kì í ṣe Ọlọrun àfonífojì,” nítorí náà ni n óo ṣe fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí ọ̀pọ̀ eniyan wọnyi, o óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Enia Ọlọrun kan si wá, o si sọ fun ọba Israeli, o si wipe, Bayi li Oluwa wi, Nitoriti awọn ara Siria wipe, Oluwa, Ọlọrun oke ni, ṣugbọn on kì iṣe Ọlọrun afonifoji, nitorina emi o fi gbogbo ọ̀pọlọpọ enia yi le ọ lọwọ́, ẹnyin o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ènìyàn Ọlọ́run kan sì gòkè wá, ó sì sọ fún ọba Ísírẹ́lì pé, “Báyìí ni OLÚWA wí: ‘Nítorí tí àwọn ará Árámù rò pé OLÚWA, Ọlọ́run òkè ni, ṣùgbọ́n òun kì í ṣe Ọlọ́run àfonífojì, nítorí náà èmi ó fi gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yìí lé ọ lọ́wọ́, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni OLÚWA.’ ”