1 Kings 20:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àgọ́ àwọn ọmọ ogun Israẹli ati ti àwọn ọmọ ogun Siria kọjú sí ara wọn, wọn kò sì kúrò ní ààyè wọn fún ọjọ́ meje. Nígbà tí ó di ọjọ́ keje wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jagun. Àwọn ọmọ ogun Israẹli pa ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ọmọ ogun tí wọn ń fi ẹsẹ̀ rìn lára àwọn ti Siria ní ọjọ́ kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si dó, ekini tì ekeji ni ijọ meje. O si ṣe, li ọjọ keje, nwọn padegun, awọn ọmọ Israeli si pa ọkẹ marun ẹlẹsẹ̀ ninu awọn ara Siria li ọjọ kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì dó ṣíwájú ara wọn fún ọjọ́ méje, àti ní ọjọ́ keje, wọ́n pàdé ogun. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì pa ọ̀kẹ́ márùn ún (100,000) ẹlẹ́sẹ̀ nínú àwọn ará Árámù ní ọjọ́ kan.