1 Kings 20:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ ogun Siria yòókù sì sá lọ sí ìlú Afeki; odi ìlú náà sì wó pa ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaarin (27,000) tí ó kù ninu wọn. Benhadadi pàápàá sá wọ inú ìlú lọ, ó sì sá pamọ́ sinu yàrá ní ilé kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sugbọn awọn iyokù salọ si Afeki, sinu ilu; odi si wolu ẹgbamẹtala-le-ẹgbẹrun ninu awọn enia ti o kù. Benhadadi si sa lọ, o si wá sinu ilu lati iyẹwu de iyẹwu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn tókù sì sá àsálà lọ sí Áfékì, sínú ìlú tí odi ti wó lù ẹgbàámẹ́talá-lé ẹgbẹ̀rún nínú wọn. Bẹni-Hádádì sì sá lọ sínú ìlú, ó sì fara pamọ́ sínú ìyẹ̀wù.