1 Kings 20:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, wọ́n sán aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́dìí, wọ́n sì wé okùn mọ́ ara wọn lórí. Wọ́n bá tọ Ahabu ọba lọ, wọ́n ní, “Benhadadi, iranṣẹ rẹ, ní kí á jíṣẹ́ fún ọ pé kí o jọ̀wọ́ kí o dá ẹ̀mí òun sí.” Ahabu bá dáhùn pé, “Ó ṣì wà láàyè? Arakunrin mi ni!”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni nwọn di aṣọ ọ̀fọ mọ ẹgbẹ wọn, nwọn si fi ijara yi ori wọn ka, nwọn si tọ̀ ọba Israeli wá, nwọn si wipe, Benhadadi, iranṣẹ rẹ, wipe, Emi bẹ ọ, jẹ ki ẹmi mi ki o yè. On si wipe, O mbẹ lãye sibẹ? arakunrin mi li on iṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ wọn, Wọ́n sì fi okùn yí orí wọn ká, wọ́n sì tọ ọba Ísírẹ́lì wá, wọ́n sì wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ Bẹni-hádádì wí pé, ‘Èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́kí èmi kí ó yè.’ ” Ọba sì dáhùn wí pé, “Ó ń bẹ láàyè bí? Arákùnrin mi ni òun.”