1 Kings 20:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn iranṣẹ Benhadadi ti ń ṣọ́ Ahabu fún àmì rere kan tẹ́lẹ̀. Nígbà tí Ahabu ti fẹnu kan “Arakunrin”, kíá ni wọ́n ti gba ọ̀rọ̀ yìí mọ́ ọn lẹ́nu, wọ́n ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, arakunrin rẹ ni Benhadadi.” Ahabu wí fún wọn pé, “Ẹ lọ mú un wá.” Nígbà tí Benhadadi dé, Ahabu ní kí ó wọ inú kẹ̀kẹ́ ogun pẹlu òun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọkunrin na si ṣe akiyesi gidigidi, nwọn si yara gbá ohun ti o ti ọdọ rẹ̀ wá mu: nwọn si wipe, Benhadadi arakunrin rẹ! Nigbana li o wipe, Ẹ lọ mu u wá. Nigbana ni Benhadadi jade tọ̀ ọ wá; o si mu u goke wá sinu kẹkẹ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọkùnrin náà sì ṣe àkíyèsí gidigidi, wọ́n sì yára gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, wọ́n sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹni-Hádádì arákùnrin rẹ.” Ọba sì wí pé, “Ẹ lọ mú u wá.” Nígbà tí Bẹni-Hádádì jáde tọ̀ ọ́ wá, Áhábù sì mú u gòkè wá sínú kẹ̀kẹ́.