1 Kings 20:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Benhadadi bá wí fún un pé, “N óo dá àwọn ìlú tí baba mi gbà lọ́wọ́ baba rẹ pada fún ọ, o óo sì lè kọ́ àwọn ilé ìtajà fún ara rẹ ní ìlú Damasku gẹ́gẹ́ bí baba mi ti ṣe ní ìlú Samaria.” Ahabu dá a lóhùn pé, “Bí o bá ṣe ohun tí o wí yìí, n óo dá ọ sílẹ̀.” Ahabu bá bá a dá majẹmu, ó sì fi sílẹ̀ kí ó máa lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wi fun u pe, Awọn ilu ti baba mi gbà lọwọ baba rẹ, emi o mu wọn pada: iwọ o si là ọ̀na fun ara rẹ ni Damasku, bi baba mi ti ṣe ni Samaria. Nigbana ni Ahabu wipe, Emi o rán ọ lọ pẹlu majẹmu yi. Bẹ̃ li o ba a dá majẹmu, o si rán a lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹni-Hádádì sì wí pé, “Èmi yóò dá àwọn ìlú tí baba mi ti gbà lọ́wọ́ baba rẹ padà, ìwọ sì le la ọ̀nà fún ara rẹ ní Dámáskù, bí baba mi ti ṣe ní Samáríà.” Áhábù sì wí pé, “Èmi yóò rán ọ lọ pẹ̀lú májẹ̀mú yìí.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ba dá májẹ̀mú, ó sì rán an lọ.