1 Kings 20:39 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ọba ti ń kọjá lọ, wolii yìí kígbe pé, “Kabiyesi, nígbà tí mò ń jà lójú ogun, ọmọ ogun ẹlẹgbẹ́ mi kan mú ọ̀tá kan tí ó mú ní ìgbèkùn wá sọ́dọ̀ mi, ó ní kí n máa ṣọ́ ọkunrin yìí, ó ní bí ó bá sá lọ, èmi ni n óo kú dípò rẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, mo níláti san ìwọ̀n talẹnti fadaka kan gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ọba si ti nkọja lọ, o ke si ọba o si wipe, iranṣẹ rẹ jade wọ arin ogun lọ; si kiyesi i, ọkunrin kan yà sapakan, o si mu ọkunrin kan fun mi wá o si wipe: Pa ọkunrin yi mọ; bi a ba fẹ ẹ kù, nigbana ni ẹmi rẹ yio lọ fun ẹmi rẹ̀, bi bẹ̃ kọ, iwọ o san talenti fadaka kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ọba sì ti ń ré kọjá, wòlíì náà ké sí i, ó sì wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ jáde wọ àárin ogun lọ, ẹnìkan sì wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ìgbékùn kan, ó sì wí pé, ‘Pa ọkùnrin yìí mọ́. Bí a bá fẹ́ ẹ kù, ẹ̀mi rẹ yóò lọ dípò ẹ̀mí rẹ̀, tàbí kí ìwọ san talẹ́ǹtì fàdákà kan.’