1 Kings 20:40 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn níbi tí mo ti ń lọ sókè sódò, tí mò ń ṣe àwọn nǹkan mìíràn, ọkunrin yìí sá lọ.” Ọba dá a lóhùn pé, “Ìwọ náà ti dá ara rẹ lẹ́jọ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni yóo sì rí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi iranṣẹ rẹ si ti ni iṣe nihin ati lọhun, a fẹ ẹ kù. Ọba Israeli si wi fun u pe, Bẹ̃ni idajọ rẹ yio ri: iwọ tikararẹ ti dá a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ sì ní ìṣe níhìn ín àti lọ́hùn ún, a fẹ́ ẹ kù.” Ọba Ísírẹ́lì sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ìdájọ́ rẹ yóò rí, ìwọ fúnra rẹ ti dá a.”