1 Kings 20:42 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wolii náà bá wí fún ọba pé, “OLUWA ní, nítorí pé o jẹ́ kí ẹni tí mo ti pinnu láti pa sá lọ, ẹ̀mí rẹ ni n óo fi dípò ẹ̀mí rẹ̀, n óo sì pa àwọn eniyan rẹ dípò àwọn eniyan rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, nitoriti iwọ jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ, ọkunrin ti emi ti yàn si iparun patapata, ẹmi rẹ yio lọ fun ẹmi rẹ̀, ati enia rẹ fun enia rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún ọba pé, “Báyìí ni OLÚWA wí: ‘Ìwọ ti jọ̀wọ́ ọkùnrin tí èmi ti yàn sí ìparun pátapáta lọ́wọ́ lọ. Nítorí náà, ẹ̀mí rẹ yóò lọ fún ẹ̀mí rẹ, ènìyàn rẹ fún ènìyàn rẹ̀.’ ”