1 Kings 20:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ṣugbọn òun óo rán àwọn oníṣẹ́ òun sí i ní ìwòyí ọ̀la láti yẹ ààfin rẹ̀ wò ati ilé àwọn oníṣẹ́ rẹ̀, kí wọ́n sì kó ohunkohun tí ó bá wù wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati emi ba rán awọn iranṣẹ mi si ọ ni iwòyi ọla, nigbana ni nwọn o wá ile rẹ wò, ati ile awọn iranṣẹ rẹ; yio si ṣe, ohunkohun ti o ba dara loju rẹ, on ni nwọn o fi si ọwọ́ wọn, nwọn o si mu u lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ní ìwòyí ọ̀la Èmi yóò rán àwọn ìránṣẹ́ mi sí ọ láti wá ilé rẹ wò àti ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ. Wọn yóò gba gbogbo ohun tí ó bá dára lójú rẹ, wọn yóò sì kó o lọ.’ ”