1 Kings 20:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà ni Ahabu ọba ranṣẹ pe gbogbo àwọn àgbààgbà ilẹ̀ náà, ó wí fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí i pé ọkunrin yìí ń wá ìjàngbọ̀n? Ó ranṣẹ wá pé kí n kó fadaka ati wúrà mi, ati àwọn obinrin mi, ati àwọn ọmọ mi fún òun, n kò sì bá a jiyàn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ọba Israeli pè gbogbo awọn àgba ilu, o si wipe, Ẹ fiyèsi i, emi bẹ̀ nyin, ki ẹ si wò bi ọkunrin yi ti nfẹ́ ẹ̀fẹ: nitoriti o ranṣẹ si mi fun awọn aya mi, ati fun awọn ọmọ mi, ati fun fadaka mi, ati fun wura mi, emi kò si fi dù u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ọba Ísírẹ́lì pe gbogbo àwọn àgbà ìlú, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wo bí ọkùnrin yìí ti ń fẹ́ ìyọnu! Nígbà tí ó ránṣẹ́ fún àwọn aya mi, àti fún àwọn ọmọ mi, àti fún fàdákà mi, àti fún wúrà mi, èmi kò sì fi dù ú.”