1 Kings 20:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ahabu bá ranṣẹ pada sí Benhadadi ọba pé, “Mo faramọ́ ohun tí ó kọ́kọ́ bèèrè fún, ṣugbọn n kò lè gba ti ẹẹkeji yìí.” Àwọn oníṣẹ́ náà pada lọ jíṣẹ́ fún Benhadadi ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina li o sọ fun awọn onṣẹ Benhadadi pe, Wi fun oluwa mi ọba pe, ohun gbogbo ti iwọ ranṣẹ fun, sọdọ iranṣẹ rẹ latetekọṣe li emi o ṣe: ṣugbọn nkan yi li emi kò le ṣe. Awọn onṣẹ na pada lọ, nwọn si tun mu èsi fun u wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn oníṣẹ́ Bẹni-Hádádì pé, “Sọ fún OLÚWA mi ọba pé, ‘Ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe ohun gbogbo tí ó ránṣẹ́ fún látètèkọ́ṣe, ṣùgbọ́n nǹkan yìí ni èmi kò le ṣe.’ ” Wọ́n padà lọ, wọ́n sì mú èsì padà wá fún Bẹni-hádádì.