1 Kings 21:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí ẹ wá àwọn eniyankeniyan meji kan tí wọ́n ya aṣa, kí wọ́n jókòó níwájú rẹ̀, kí wọ́n sì fi ẹ̀sùn kàn án pé, ó bú Ọlọrun ati ọba. Lẹ́yìn náà, ẹ mú un jáde sẹ́yìn odi ìlú, kí ẹ sì sọ ọ́ lókùúta pa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹ fi enia meji, ẹni buburu, siwaju rẹ̀ lati jẹri pa a, wipe, Iwọ bu Ọlọrun ati ọba. Ẹ mu u jade, ki ẹ si sọ ọ li okuta ki o le kú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n kí ẹ fi ènìyàn méjì, ẹni búburú ṣíwájú rẹ̀ láti jẹ́rìí pa á wí pé, ó bú Ọlọ́run àti ọba. Nígbà náà ni kí ẹ mú u jáde, kí ẹ sì sọ ọ́ ní òkúta pa.”