1 Kings 21:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn eniyankeniyan meji tí wọ́n ya aṣa yìí jókòó níwájú rẹ̀, wọ́n sì purọ́ mọ́ ọn lójú gbogbo eniyan pé ó bú Ọlọrun ati ọba. Wọ́n bá fà á jáde sẹ́yìn odi ìlú, wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta pa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkunrin meji si de, awọn ẹni buburu, nwọn si joko niwaju rẹ̀: awọn ọkunrin buburu si jẹri pa a, ani si Naboti, niwaju awọn enia wipe: Naboti bu Ọlọrun ati ọba. Nigbana ni nwọn mu u jade kuro ni ilu, nwọn si sọ ọ li okuta, o si kú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin méjì sì dé, àwọn ẹni búburú, wọ́n sì jókòó ṣíwájú rẹ̀, wọ́n sì jẹ́rìí pa Nábótì níwájú àwọn ènìyàn wí pé, “Nábótì ti bú Ọlọ́run àti ọba.” Nígbà náà ni wọ́n mú jáde kúrò ní ìlú, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa.