1 Kings 21:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí Jesebẹli ti gbọ́ pé wọ́n ti sọ Naboti lókùúta pa, ó sọ fún Ahabu pé, “Gbéra nisinsinyii, kí o sì lọ gba ọgbà àjàrà tí Naboti kọ̀ láti tà fún ọ, nítorí pé ó ti kú.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati Jesebeli gbọ́ pe, a sọ Naboti li okuta, o si kú, Jesebeli sọ fun Ahabu pe, Dide! ki o si jogun ọgba-ajara Naboti, ara Jesreeli, ti o kọ̀ lati fi fun ọ fun owo; nitori Naboti kò si lãye ṣugbọn o kú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí Jésébélì sì ti gbọ́ pé, a ti sọ Nábótì ní Òkúta pa, ó sì wí fún Áhábù pé, “Dìde! Kí o sì jogún ọgbà àjàrà Nábótì, ará Jésérẹ́lì, tí ó kọ̀ láti tà fún ọ kò sí láàyè mọ́, ó ti kú.”