1 Kings 21:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sọ pé, OLUWA ní kí o sọ fún un pé ṣé o ti pa ọkunrin yìí, o sì ti gba ọgbà àjàrà rẹ̀? Wí fún un pé, mo ní, ibi tí ajá ti lá ẹ̀jẹ̀ Naboti gan-an ni ajá yóo ti lá ẹ̀jẹ̀ tirẹ̀ náà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi: Iwọ ti pa, iwọ si ti jogun pẹlu? Iwọ o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi pe, Ni ibi ti ajá gbe lá ẹ̀jẹ Naboti, ni awọn ajá yio lá ẹ̀jẹ rẹ, ani tirẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sọ fún un pé, ‘Báyìí ni OLÚWA wí: Ǹjẹ́ ìwọ kò ti pa ènìyàn, o sì ti fi agbára gba ogún rẹ̀?’ Nígbà náà ni kí o wí fún un pé, ‘Báyìí ni OLÚWA wí: Níbi tí ajá gbé lá ẹ̀jẹ̀ Nábótì, ni àwọn ajá yóò lá ẹ̀jẹ̀ rẹ, àní tìrẹ!’ ”