1 Kings 21:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ǹjẹ́ o ṣe akiyesi bí Ahabu ti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi? Nítorí pé ó ti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ báyìí, n kò ní jẹ́ kí ibi tí mo wí ṣẹlẹ̀ nígbà ayé rẹ̀. Ó di ìgbà ayé ọmọ rẹ̀ kí n tó jẹ́ kí ibi ṣẹlẹ̀ sí ìdílé rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ ri bi Ahabu ti rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju mi? Nitori ti o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju mi, emi kì yio mu ibi na wá li ọjọ rẹ̀: li ọjọ ọmọ rẹ̀ li emi o mu ibi na wá sori ile rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ǹjẹ́ ìwọ ti rí bí Áhábù ti rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi? Nítorí tí ó ti rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀, èmi kì yóò mú ibi náà wá ní ọjọ́ rẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò mú u wá sí ilé rẹ̀ ní ọjọ́ ọmọ rẹ̀.”