1 Kings 21:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ahabu bá pada lọ sílé pẹlu ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ati ibinu, nítorí ohun tí Naboti ará Jesireeli wí fún un. Ó dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀, ó kọjú sí ògiri, kò sì jẹun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ahabu si wá si ile rẹ̀, o wugbọ, inu rẹ̀ si bajẹ nitori ọ̀rọ ti Naboti, ara Jesreeli, sọ fun u: nitoriti on ti wipe, emi kì o fun ọ ni ogún awọn baba mi. On si dubulẹ lori akete rẹ̀, o si yi oju rẹ̀ padà, kò si fẹ ijẹun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Áhábù sì wá sí ilé rẹ̀, ó wugbọ́, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí ọ̀rọ̀ tí Nábótì ará Jésérẹ́lì sọ fún un; nítorí tí ó wí pé, “Èmi kì yóò fún ọ ní ogún àwọn bàbá mi.” Ó sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀, ó sì yí ojú rẹ̀ padà, kò sì fẹ́ jẹun.