1 Kings 21:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jesebẹli bá kọ ìwé ní orúkọ Ahabu, ó fi òǹtẹ̀ Ahabu tẹ̀ ẹ́, ó fi ranṣẹ sí àwọn àgbààgbà ati àwọn eniyan ńláńlá ní ìlú tí Naboti ń gbé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni o kọwe li orukọ Ahabu, o si fi èdidi rẹ̀ di i, o si fi iwe na ṣọwọ sọdọ awọn àgbagba ati awọn ọlọla ti mbẹ ni ilu rẹ̀, ti o si mba Naboti gbe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni ó kọ̀wé ní orúkọ Áhábù, ó sì fi èdìdì rẹ̀ dì í, ó sì fi ìwé náà ránṣẹ́ sí àwọn àgbààgbà àti àwọn ọlọ́lá tí ó ń gbé ní ìlú Nábótì pẹ̀lú rẹ̀.