1 Kings 22:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀kan ninu wọn tí ń jẹ́ Sedekaya, ọmọ Kenaana fi irin ṣe ìwo, ó sì wí fún Ahabu pé, “OLUWA ní kí n wí fún ọ pé, ohun tí ìwọ óo fi bá àwọn ará Siria jà nìyí títí tí o óo fi ṣẹgun wọn patapata.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sedekiah, ọmọ Kenaana si ṣe iwo irin fun ara rẹ̀, o si wipe: Bayi li Oluwa wi, Wọnyi ni iwọ o fi kàn ara Siria titi iwọ o fi run wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣedekíà ọmọ Kénáánà sì ṣe ìwo irin fún ara rẹ̀, ó sì wí pé, “Báyìí ni OLÚWA wí: ‘Wọ̀nyí ni ìwọ yóò fi kan àwọn ará Árámù títí ìwọ yóò fi run wọ́n.’ ”