1 Kings 22:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Iranṣẹ tí ọba rán lọ pe Mikaaya wí fún un pé, “Gbogbo àwọn wolii yòókù ni wọ́n ti fi ohùn ṣọ̀kan tí wọ́n sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere fún ọba, ìwọ náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ó bá tiwọn mu, kí o sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Onṣẹ ti o lọ ipè Mikaiah wi fun u pe, Kiyesi i nisisiyi, ẹnu kanna ni ọ̀rọ awọn woli fi jẹ rere fun ọba: emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o dabi ọ̀rọ ọkan ninu wọn, ki o si sọ rere.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìránṣẹ́ tí ó lọ pe Míkáyà wí fún un pé, “Wò ó, ẹnu kan náà ni ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì fi jẹ́ rere fún ọba. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ bá ti àwọn tókù mu, kí o sì sọ rere.”