1 Kings 22:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mikaaya bá dáhùn pé, “Mo rí àwọn ọmọ ogun Israẹli tí wọ́n fọ́n káàkiri gbogbo orí òkè, bí aguntan tí kò ní olùṣọ́. OLUWA sì wí pé, ‘Àwọn eniyan wọnyi kò ní olórí, kí olukuluku wọn pada lọ sí ilé ní alaafia.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wipe, Mo ri gbogbo Israeli tukakiri lori awọn oke bi agutan ti kò ni oluṣọ: Oluwa si wipe, Awọn wọnyi kò ni oluwa, jẹ ki nwọn ki o pada olukuluku si ile rẹ̀ li alafia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Míkáyà sì dáhùn pé, “Mo rí gbogbo Ísírẹ́lì túkáàkiri lórí àwọn òkè bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́, OLÚWA sì wí pé, ‘Àwọn wọ̀nyí kò ní olúwa. Jẹ́ kí olúkúlùkù padà sí ilé rẹ̀ ní àlàáfíà.’ ”