1 Kings 22:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sedekaya wolii, ọmọ Kenaana bá súnmọ́ Mikaaya, ó gbá a létí, ó ní, “Ọ̀nà wo ni Ẹ̀mí OLUWA gbà fi mí sílẹ̀, tí ó sì ń bá ìwọ sọ̀rọ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Sedekiah, ọmọ Kenaana sunmọ ọ, o si lu Mikaiah li ẹ̀rẹkẹ, o si wipe, Ọ̀na wo li ẹmi Oluwa gbà lọ kuro lọdọ mi lati ba ọ sọ̀rọ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ṣedekíàh ọmọ Kénáánà sì dìde, ó sì gbá Míkáyàh lójú, ó sì wí pé, “Ọ̀nà wo ni ẹ̀mí OLÚWA gbà lọ kúrò lọ́dọ̀ mi láti bá ọ sọ̀rọ̀?”