1 Kings 22:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Siria déédé ta ọfà rẹ̀, ọfà náà sì bá Ahabu ọba níbi tí àwọn irin ìgbàyà rẹ̀ ti fi ẹnu ko ara wọn. Ó bá wí fún ẹni tí ń wa kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ pé kí ó gbé òun kúrò lójú ogun, nítorí pé òun ti fara gbọgbẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkunrin kan si fà ọrun rẹ̀ laipete, o si ta ọba Israeli lãrin ipade ẹwu-irin; nitorina li o ṣe wi fun olutọju-kẹkẹ́ rẹ̀ pe, Yi ọwọ́ rẹ dà, ki o si mu mi jade kuro ninu ogun; nitoriti emi gbọgbẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ẹnìkan sì fa ọrun rẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, ó sì ta ọba Ísírẹ́lì láàrin ìpàdé ẹ̀wù irin. Ọba Ísírẹ́lì sì wí fún olùtọ́jú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ pé, “Yí ọwọ́ rẹ dà, kí o sì mú mi jáde kúrò nínú ogun. Èmi ti gbọgbẹ́.”