1 Kings 22:43 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ohun tí ó dára lójú OLUWA, tí Asa baba rẹ̀ ṣe ni òun náà ṣe; ṣugbọn kò wó àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí wọ́n wà káàkiri. Àwọn eniyan tún ń rúbọ, wọ́n sì tún ń sun turari níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si rin ni gbogbo ọ̀na Asa baba rẹ̀; kò yipada kuro ninu rẹ̀, o nṣe eyiti o tọ li oju Oluwa: kiki a kò mu awọn ibi giga kuro; awọn enia si nrú ẹbọ, nwọn si nsun turari sibẹ̀ ni ibi giga wọnni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì rìn nínú gbogbo ọ̀nà Áṣà baba rẹ̀, kò sì yípadà kúrò nínú rẹ̀; ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú OLÚWA. Kìkì àwọn ibi gíga ni a kò mú kúrò, àwọn ènìyàn sì ń rú ẹbọ, wọ́n sì ń sun tùràrí níbẹ̀.