1 Kings 22:50 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó yá, Jehoṣafati kú, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn ọba, ní ìlú Dafidi, baba ńlá rẹ̀. Jehoramu ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè dípò rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jehoṣafati si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi, baba rẹ̀: Jehoramu, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Jèhósáfátì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dáfídì, baba rẹ. Jéhórámù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.