1 Kings 22:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ahabu ọba Israẹli bá pe àwọn wolii bí irinwo (400) jọ, ó bi wọ́n pé ṣé kí òun lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi àbí kí òun má lọ? Wọ́n dá a lóhùn pé, “Máa lọ, nítorí OLUWA yóo jẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ̀ ẹ́, yóo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ọba Israeli kó awọn woli jọ, bi irinwo ọkunrin, o si wi fun wọn pe, Ki emi ki o ha lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki emi ki o jọwọ rẹ̀? Nwọn si wipe, Goke lọ: nitoriti Oluwa yio fi i le ọba lọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ọba Ísírẹ́lì kó àwọn wòlíì jọ, bí irinwó (400) ọkùnrin. Ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣé kí n lọ sí Ramoti-Gílíádì lọ jagun, tàbí kí èmi kí ó jọ̀wọ́ rẹ̀?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Lọ, nítorí tí OLÚWA yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”