1 Kings 22:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ahabu dá a lóhùn pé, “Ẹnìkan tí ó kù, tí ó tún lè bá wa wádìí lọ́dọ̀ OLUWA ni Mikaaya ọmọ Imila, ṣugbọn mo kórìíra rẹ̀; nítorí pé kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi rí, àfi burúkú.” Jehoṣafati dá a lóhùn pé, “Kabiyesi, má wí bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, ọkunrin kan Mikaiah, ọmọ Imla, mbẹ sibẹ, lọdọ ẹniti awa iba bère lọwọ Oluwa: ṣugbọn emi korira rẹ̀, nitori kì isọ asọtẹlẹ ire si mi, bikoṣe ibi. Jehoṣafati si wipe, Ki ọba má sọ bẹ̃.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba Ísírẹ́lì dá Jèhóṣáfátì lóhùn pé, “Ọkùnrin kan sì wà, lọ́dọ̀ ẹni tí àwa lè béèrè lọ́wọ́ OLÚWA, ṣùgbọ́n mo kórìíra rẹ̀ nítorí kì í sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere kan nípa mi, bí kò ṣe ibi. Míkáyà ọmọ Ímílà ni.” Jéhósáfátì sì wí pé, “Kí ọba má ṣe sọ bẹ́ẹ̀.”