1 Kings 3:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Solomoni gbé ọmọ Farao, ọba Ijipti níyàwó, ó fi bá ọba Farao dá majẹmu àjọṣepọ̀ láàrin wọn. Solomoni mú iyawo náà wá sí ìlú Dafidi títí tí ó fi parí ààfin rẹ̀ ati ilé OLUWA tí ó ń kọ́, ati odi Jerusalẹmu tí ó ń mọ lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
SOLOMONI si ba Farao ọba Egipti da ana, o si gbe ọmọbinrin Farao ni iyawo, o si mu u wá si ilu Dafidi, titi o fi pari iṣẹ ile rẹ̀, ati ile Oluwa, ati odi Jerusalemu yika.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sólómónì sì bá Fáráò ọba Éjíbítì dá àna, ó sì fẹ́ ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìyàwó. Ó sì mú-un wá sí ìlú Dáfídì títí tí ó fi parí kíkọ́ ààfin rẹ̀ àti tẹ́ḿpìlì OLÚWA, àti odi tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká.