1 Kings 3:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Solomoni tají, ó rí i pé àlá ni òun ń lá, ó bá lọ sí Jerusalẹmu, ó lọ siwaju Àpótí Ẹ̀rí OLUWA, ó sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia sí OLUWA. Lẹ́yìn náà, ó se àsè ńlá fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Solomoni si jí; si wò o, alá ni. On si wá si Jerusalemu, o si duro niwaju apoti majẹmu Oluwa, o si rubọ ọrẹ sisun, o si ru ẹbọ-alafia, o si se àse fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sólómónì jí: ó sì mọ̀ pé àlá ni. Ó sì padà sí Jérúsálẹ́mù, ó sì dúró níwájú àpótí májẹ̀mú OLÚWA, ó sì rúbọ ọrẹ sísun àti ẹbọ àlàáfíà. Nígbà náà ni ó ṣe àṣè fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ.