1 Kings 3:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọjọ́ kẹta tí mo bí ọmọ tèmi ni obinrin yìí náà bí ọmọkunrin kan. Àwa meji péré ni a wà ninu ilé, kò sí ẹnìkẹta pẹlu wa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe ni ọjọ kẹta lẹhin igbati mo bimọ tan, obinrin yi si bimọ pẹlu: awa si jumọ ngbé pọ: kò si si alejo pẹlu wa ni ile bikoṣe awa mejeji ni ile.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn ìgbà tí mo bímọ tan, obìnrin yìí sì bímọ pẹ̀lú. A sì nìkan dá wà; kò sí ẹlòmíràn ní ilé bí kò ṣe àwa méjèèjì nìkan.