1 Kings 3:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọkàn ìyá tí ó ni ààyè ọmọ kò gbà á, nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí ọmọ rẹ̀, ó wí fún ọba pé, “Kabiyesi, gbé ààyè ọmọ yìí fún ekeji mi, má pa á rárá.” Ṣugbọn èyí ekeji dáhùn pé, “Rárá! Kò ní jẹ́ tèmi, kò sì ní jẹ́ tìrẹ. Jẹ́ kí wọ́n là á sí meji.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Obinrin ti eyi alãye ọmọ iṣe tirẹ̀ si wi fun ọba, nitori ti inu rẹ̀ yọ́ si ọmọ rẹ̀, o si wipe, Jọwọ, oluwa mi, ẹ fun u ni eyi alãye ọmọ, ki a máṣe pa a rara. Ṣugbọn eyi ekeji si wipe, kì yio jẹ temi tabi tirẹ, ẹ là a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Obìnrin tí ọmọ tirẹ̀ wà láàyè sì kún fún àánú fún ọmọ rẹ̀, ó sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, OLÚWA mi, ẹ fún un ní alààyè ọmọ! Ẹ má ṣe pa á!” Ṣùgbọ́n obìnrin èkejì sì wí pé, “Kì yóò jẹ́ tèmi tàbí tìrẹ̀. Ẹ gé e sí méjì!”