1 Kings 3:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun mi, ìwọ ni o jẹ́ kí èmi iranṣẹ rẹ gun orí oyè lẹ́yìn baba mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọde ni mí, n kò sì mọ̀ bí wọ́n ti ń ṣe àkóso.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun mi, iwọ ti fi iranṣẹ rẹ jẹ ọba ni ipo Dafidi, baba mi: ati emi, ọmọ kekere ni mi, emi kò si mọ̀ jijade ati wiwọle.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nísinsìnyìí, OLÚWA Ọlọ́run mi, o ti mú ìránṣẹ́ rẹ jọba ní ipò Dáfídì baba mi. Ṣùgbọ́n ọmọ kékeré ni mí, èmi kò sì mọ̀ bí mo ṣe lè ṣe àwọn ojúṣe mi.